Isaiah 50

Ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli àti ìgbọ́ràn ìránṣẹ́

1Ohun tí Olúwa wí nìyìí:

“Níbo ni ìwé-ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ ìyá rẹ wà
èyí tí mo fi lé e lọ?
Tàbí èwo nínú àwọn olùyánilówó mi
ni mo tà ọ́ fún?
Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ni a fi tà ọ́;
nítorí àìṣedéédéé rẹ ni a fi lé ìyá rẹ lọ.
2Nígbà tí mo wá, èéṣe tí a kò fi rí ẹnìkan?
Nígbà tí mo pè, èéṣe tí kò fi sí ẹnìkan láti dáhùn?
Ọwọ́ mi a kúrú láti gbà ọ́?
Èmi kò ha ní agbára láti gbà ọ́ bí?
Nípa ìbáwí lásán, Èmi gbẹ omi Òkun,
Èmi yí àwọn odò sí aṣálẹ̀;
àwọn ẹja wọn rà fún àìsí omi
wọ́n sì kú fún òǹgbẹ.
3Èmi fi òkùnkùn bo sánmọ̀
mo sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ ṣe ìbòrí rẹ̀.”

4 Olúwa Olódùmarè ti fún mi ni ahọ́n tí a fi iṣẹ́ rán,
láti mọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lè gbé àwọn aláàárẹ̀ ró.
O jí mi láràárọ̀,
o jí etí mi láti gbọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí à ń kọ́.
5 Olúwa Olódùmarè ti ṣí mi ní etí,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ṣọ̀tẹ̀ rí;
Èmi kò sì padà sẹ́yìn.
6Mo ṣí ẹ̀yìn mi sílẹ̀ fún àwọn tí ó ń nà mí,
àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi fún àwọn tí ń fa irùngbọ̀n mi;
Èmi kò fi ojú mi pamọ́
kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́yà àti ìyọṣùtì sí.
7Nítorí Olúwa Olódùmarè ràn mí lọ́wọ́;
A kì yóò dójútì mí.
Nítorí náà ni mo ṣe gbé ojú mi ró bí òkúta akọ
èmi sì mọ pé, ojú kò ní tì mí.
8Ẹni tí ó dá mi láre wà nítòsí.
Ta ni ẹni náà tí yóò fẹ̀sùn kàn mí?
Jẹ́ kí a kojú ara wa!
Ta ni olùfisùn mi?
Jẹ́ kí ó kò mí lójú!
9 Olúwa Olódùmarè ni ó ń ràn mí lọ́wọ́.
Ta ni ẹni náà tí yóò dá mi lẹ́bi?
Gbogbo wọn yóò gbó bí aṣọ;
kòkòrò ni yóò sì jẹ wọn run.

10Ta ni nínú yín tí ó bẹ̀rù Olúwa
tí ó sì ń gbọ́rọ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nu?
Jẹ́ kí ẹni tí ń rìn ní òkùnkùn
tí kò ní ìmọ́lẹ̀,
kí ó gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa
kí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run rẹ̀.
11Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí, gbogbo ẹ̀yin ti ń tanná
tí ẹ sì ń fi pèsè iná ìléwọ́ fún ara yín,
ẹ lọ, kí ẹ sì máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ iná yín,
àti nínú ẹta iná tí ẹ ti dá.
Èyí ni yóò jẹ́ tiyín láti ọwọ́ mi wá:
Ẹ̀yin ó dùbúlẹ̀ nínú ìrora.
Copyright information for YorBMYO